Oríkì Ìlú Ìjẹ̀bú|The Eulogy of Ijebu Town|AbalayeTV
Ìjẹ̀bú ọmọ Alárẹ̀,Ọmọ Bíbíire è é è jú fowórà,Ọmọ Aṣàlèjẹ̀jẹ̀ bọ́ọni nòóbìnrin,Ẹ̀yin ọmọLúwàbí,Ọmọ Olú-ìwà,Ọmọ Ọbańta,Ọmọ Alárẹ̀.Ọmọ Alágẹmọ-ò-tú-yọ̀wọ̀yọ̀wọ̀.Ọmọ b'épè ò jà mọ́,Má yáa wóhun mín ìn tún ṣe.Ìjẹ̀bú ọmọ Arójòjoyè.Ọmọ Awúre fàṣẹ banu.Ọmọ olówó joyè méjì pọ̀.Olówó ṣílè ṣá lẹ̀yin,Kékeré Ìjẹ̀bú, owó ni.Àgbà Ìjẹ̀bú, owó ni.Ọmọ Àrígbá-ńlá-buwó,Ọmọ A fọ́nwó bí ẹ ń fọ́n yangan.Ìjẹ̀bú ọmọ A-fìdí-pọ̀tẹ̀ mọlẹ̀.Iṣu mẹ́fà nisu Ìjẹ̀bú,Wọ́n ta méjì,Wọ́n jẹ méjì síkùn ara wọn,Ó l'órìṣà tí wọ́n fi méjì yókù bọ.Ọmọ ẹlẹ́dìẹ òkòkòmàgà,Èyí tí ń mingbó kìjikìji.Ọmọ ohun ń ṣe ni ọ̀yọ̀yọ̀ ń yọ̀,Ọ̀yọ̀yọ̀ má yọ̀ má yọ̀ mọ́,Ohun tó ń ṣeni ò ní lè pani.Ọmọ Ọlọ́pẹ kan ọ̀jẹ́gẹ́tirígẹ́,Ọmọ Ọlọ́pẹ kan ọ̀jẹ̀gẹ̀tirígẹ̀,Kò ga jù, bẹ́ẹ̀ ni kò kúrú,Ó ń fọwọ́ imọ̀ gbálẹ̀ gẹẹrẹgẹ.Afínjú Ìjẹ̀bú tí í fọkọ ẹ̀ j'Apènà.Ààyè gbà'Jẹ̀bú,Ó wẹní rẹ wínníwínní,Ààyè gbà' Jẹ̀bú,Ó wẹní rẹ ní wìnnìwìnnì,Ààyè gbọmọ Ògbòrògànlúdà,Ó bẹ́mọ lórí rẹ̀gí rẹ̀gí.A-bọ́lọ́mọ-jà-bí-ò-pọnmọ-re,Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ọmọ Ò-gboko-gbààlà.Lyrics by: Lawanson, O. (2010). Àwọn Oríkì Mẹ́ta Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ; Lagos : Afbax Communications.Video by: Abalaye NaijiriaMusic by: Ebenezer Obey